Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ àpapọ̀ buwọ́lu iye owó tótó Bílíọ́nù méjì ààbọ̀ dọ́là Fún èbúté Bàdágìrì Ní Ìlú Èkó
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìgbìmọ̀ Aláse àpapọ̀ ti fọwọ́sí iye owó tí ó tó bílíọ́nù méjì ààbọ̀ dọ́là fún àtúnṣe èbúté Bàdágìrì ní Ìpínlẹ̀ Èko, gúsùùl iwọ̀ oòrùn,orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Minisita ti eto gbigbelọ ati bibọ, Muazu Sambo, ẹniti o ṣafihan eyi ni ipari ipade minisita ọsẹ yii, sọ fun Awọn oniroyin pe wọn yoo ṣe iṣẹ akanṣe naa labẹ eto ajọṣepọ aladani-tijọba.
![]()
Gẹgẹ bi o ti sọ, ile-iṣẹ aladani yoo na owo sinu ibudo naa, ati ṣakoso rẹ fun ọdun marunle-logoji.
Sambo sọ pe igbesẹ ti ijọba gbe yii yoo tunbọ mu ipinnu rẹ duro lati sọ Naijiria di ibudo okun awọn agbegbe Iwọ-oorun ati Ariwa Afirika.
Leave a Reply