Take a fresh look at your lifestyle.

Ọjọ́ Ìlera Àgbáyé: Àjọ WHO Fẹ́ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Gbogbo Àgbáyé

107

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti rọ àwọn ènìyàn kárí ayé láti tún ìdúróṣinṣin wọn sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe àti láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gẹ́gẹ́ bí agbára ìdarí fún ìdarasi ìlera àgbáyé.

Àjọ náà ké sí àwọn ìjọba, àwọn ilé iṣẹ́ àti àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan láti mú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lágbára síi kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn ọ̀nà tí ó dá lórí ẹ̀rí ń darí àwọn ìlànà ìlera àti àwọn ìpinnu ojoojúmọ́.

Àjọ WHO ro àwọn ènìyàn, èyí jẹyọ nínú gbólóhùn kan tí ó ṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Ìlera Àgbáyé ti ọdún 2026, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ni àpapọ̀ fún ìlera. Dúró pẹ̀lú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.” Ìpolongo náà ń ṣe ìrántí ìdásílẹ̀ àjọ náà ní ọjọ́ keje oṣù kẹrin, ọdún 1948, ó sì bẹ̀rẹ̀ ètò ìlera gbogbogbòò fún ọdún kàn.

WHO tẹnumọ́ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbọ́dọ̀ máa tọ́pinpin ìpinnu ìlera ní gbogbo ìpele. Àwọn alábáṣiṣẹpọ̀ rẹ̀ ń mú ẹ̀rí jáde àti túmọ̀ rẹ̀ káàkiri onírúurú àwọn ohun pàtàkì ìlera, láti àwọn àrùn àkóràn àti àwọn àìsàn onígbà pípẹ́ sí ìlera ọpọlọ, oúnjẹ àti ewu àyíká, ní ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè láti pèsè ìtọ́jú tó dára, tó tọ́.

Àwọn àṣeyọrí nínú ìlera àgbáyé fihàn pé nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá para pọ̀ lẹ́yìn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, wọ́n ń dáhùn sí àwọn ìṣòro tó lágbára jù, wọ́n sì ń kọ́ àwọn ètò ìlera tó dára púpọ̀ fún ọjọ́ iwájú.

Temitọ́pè Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button