Ẹni tó to ti gba ìwé àmì ẹ̀yẹ Guinness World Record, Kanyeyachukwu Tagbo-Okeke láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, fi ìfaradà àti ìpinnu hàn láti parí ìrìn àjò kẹ̀kẹ́ tó gùn tó ibusọ̀ to le ni ẹgbẹta Kilomita, 687KM láti Enugu sí Èkó ní Nàìjíríà, lẹ́yìn tó ti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀.
Dídé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún náà sí Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ́ àkókò pàtàkì kan, bí Gómìnà Àgbà, Babajide Sanwo-Olu, ṣe gbà á ní alejo ní ilé gomina ni Marina ilu Eko. láti fi hàn pé ó ṣe àṣeyọrí àti pé òun ṣe é dáadáa.

Bí ẹni tó gba àmì-ẹ̀yẹ àgbáyé ṣe ń padà bọ̀ sípò láti inú iṣẹ́ àrà ńlá yìí, àṣeyọrí náà dúró gẹ́gẹ́ bí àmì tuntun fún àwọn eléré ìdárayá jákèjádò agbayé, èyí tó fi hàn pé ọ̀nà sí ipò gíga sábà máa ń gba pé kí a tubọ tẹra mọọ ki a se koja ala.

Temitọ́pè Òbísẹ̀san