Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ JAMB Ní Àfojúsùn IGR To Le Ní Ogún Bílíọ̀nù Náírà Ní Ọdún 2026

68

 

Àjọ, The Joint Admissions and Matriculation Board (JAMB)
ti sọ pé wọ́n ńi àfojúsùn iye owo tó lè ní Ogún Bílíọ̀nù Náírà, N23.8 billion gẹ́gẹ́ bí oye owo tí wọn yóò rí nínú Internally Generated Revenue ((IGR) fún ọdún ìṣúná owó ọdún 2026, iye tí yóó fi biliọnu mẹrin ga jù ti esi lọ.

Aṣojú àjọ JAMB nínú ìgbékalẹ̀ rẹ̀, sọ pé láti inú o lè ní ògún biliọnu, N23.8billion IGR tí wọn fojúsùn, biliọnu mefa pere ni wọn yóò fi sínú àpò ìjọba Nàìjíríà.

Nípa ìmúrasílẹ̀ àjọ UTME ọdún 2026, Olùdarí sọ pé; “Àwọn ilé ìdánwò egberun kan ni wọn tí pèsè tí ó ga ju àwọn ilé ìdánwò ẹgbẹrin tí ọdún 2025 lọ.

Nítorí pé iṣẹ́ àjọ JAMB lábẹ́ ìdarí Ọ̀jọ̀gbọ́n Oloyede wú wọn lórí, Ìgbìmọ̀ láti Alága de àwọn ọmọ ẹgbẹ́, fún igbimo ìdánwò ní àmì to yanranti.

Ṣùgbọ́n Sẹ́nétọ̀ Yohanna Amos (Láti Ariwa Adamawa), pàṣẹ fún àjọ JAMB láti dín owó ìdánwò rẹ̀ kù láti Ẹgberun méta ààbọ̀, N3,500 tí ó jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ṣùgbọ́n Olùdarí nínú ìdáhùn rẹ̀ sọ pé owó ìdánwò náà jẹ́ Ẹgbẹrun márùn tẹlẹ, N5,000 kí wọn tó dín in kù sí Ẹgberun méta ààbọ̀, N3,500.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button