Take a fresh look at your lifestyle.

Ààwẹ̀ Ramadan: Ààrẹ Tinubu Pè Fún Ìṣọ̀kan, Àti Àlàáfíà

53

Ààrẹ Bola Tinubu ti ké sí àwọn Kristẹni àti àwọn Mùsùlùmí káàkiri orílẹ̀-èdè láti gba ìmísí láti inú kan àwọn ìlànà ẹ̀mí lasiko Lẹ́ǹtì àti Ramadan, ó ń rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbé àlàáfíà, ìṣọ̀kan Àlàáfíà láyé lásìkò yìí.

Ẹ̀bẹ̀ Ààrẹ wà nínú ìránṣẹ́ tí a kọ sí àwọn Kristẹni àti Mùsùlùmí bí àwọn àkókò mímọ́ méjèèjì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà ní ọdún yìí.

Ààrẹ Tinubu ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣọ̀wọ́n ti àwọn ayẹyẹ ìsìn méjì tí ó bẹ̀rẹ̀ ní àkókò kan náà gẹ́gẹ́ bí ìrántí agbára  ìwà rere tí  àwọn ìgbàgbọ́ pàtàkì ní  Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ojuse àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní láti gbé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan lábẹ́ Ọlọ́run.

Ó ṣe àkíyèsí pé Lẹ́ǹtì, tí àwọn Kristẹni ń ṣe, jẹ́ àkókò ààwẹ̀, àìnífaramọ́ àti ìrònúpìwàdà ní ìrántí ẹbọ Jésù Kristi àti ìmúrasílẹ̀ ẹ̀mí kí a tó kàn án mọ́ agbelebu, èyí tí ó mú ìgbàlà wá fún aráyé.

Ààrẹ ṣàlàyé wí pé Lẹ́ǹtì, tí àwọn Mùsùlùmí ń ṣe, jẹ́ àkókò mímọ́ ti ìfọkànsìn pátápátá sí Ọlọ́run Olódùmarè, tí a fi ààwẹ̀, ẹbọ, ìfọkànsìn, iṣẹ́ ìsìn sí aráyé, àti ìfẹ́ àti fífúnni lápapọ̀ hàn.

Ó fi kún un wí pé àsìkò yìí ń ṣàfihàn ọ̀kan lára àwọn òpó márùn-ún ti ẹ̀sìn Islam, ó sì ń pè fún ìrònú jinlẹ̀ nípa ẹ̀mí ju ààwẹ̀ tó pọndandan lọ.

Ààrẹ Tinubu rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti lo àwọn àsìkò mímọ́ láti fún ìṣọ̀kan lágbára síi láàárín àwọn ẹ̀sìn, láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ, àti láti tún àdúrà sọ fún ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè, ìdúróṣinṣin àti ààbò.

Ó ké sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rere ti ìgbàgbọ́ wọn, kí wọ́n sì máa jẹ́ ọlọ́lá nínú iṣẹ́ wọn sí Ọlọ́run àti sí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn.

Ààrẹ sọ ìrètí  rẹ̀  wi pé àwọn ẹ̀kọ́, ìbùkún àti ayọ̀ Lẹ́ǹtì àti Ramadan yóò mú kí àánú, ìbáwí àti ìfaramọ́ tuntun wá sí ire gbogbogbò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Comments are closed.

button