Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ké sí àwọn olórí ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìsapá ìjọba lójúnà láti ṣàṣeyọrí ìlera gbogbogbò. Ó ní, ipa wọn lórí ìbílẹ̀ jẹ́ pàtàkì sí àwùjọ àti ìṣọ̀kan tó ní ṣe pẹ̀lú gbogbo ènìyàn .

Ààrẹ náà ṣe ìpè náà ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní Àpérò Àṣà àti Àwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lórí Ìlera tí a ṣe ní Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ, Abuja.

Ààrẹ náà tún fi ìfẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ láti máa bá ogun náà lọ sí àìní ààbò, ó sì fi dá wọn lójú pé Nàìjíríà yóò ṣẹ́gun ogun náà nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.

Mínísítà fún Ìlera àti Àlàáfíà Àwùjọ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mohammed Ali Pate, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ fún fífún ní, ni ìtọ́sọ́nà ìlànà tí a nílò náà bó ṣe ṣàgbékalẹ̀ Ìròyìn Ìlera ti Ọdún 2025 kalẹ̀ fún Ààrẹ.
Comments are closed.