Àjọ, The Nigeria Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA), ti ti ilé epo pa ní ilu
Port Harcourt ipinlẹ Rivers látàri ìwà màgòmágó sì epo Pẹntiróòlù -Premium Motor Spirit (PMS).
Nígbàtí ó ní sọrọ nibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú oníròyìn ilé iṣẹ Voice of Nigeria, asaju ikọ̀ NMDPRA Retail Outlet Monitoring (ROM) unit, Ìyáàfin Ibumieghaye Ziniye, sọ pé àwọn aláṣẹ a máa mójú to àwọn ilé epo láti ri pe wọn tẹle ètò imojuto.
Bí ó ṣe sọ, ikọ̀ a máa yẹ ilé epo alagbata, iṣẹ wọn àti pé oṣuwọn ti wọn fi ń tàá ati bi wọn ṣe ń tá ti a n foju ri wò, kí onibara leè ra òdodo epo ti wọn sanwó fun.
Àwọn Awakọ̀ àti olùrà epo Pẹntiróòlù ilé epo ti ọrọ kan gboriyin fún àjọ NMDPRA fún iṣé takuntakun wọn pè ọ jẹ ìtẹ́wọ́gbà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san