Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ NSC Faramọ́ Ìgbàlejò Ìdíje Eré Gọ́ọ̀fù

17

 

Àjọ National Sports Commission (NSC), ti faramọ́ Igbalejo idije ere Gọ́ọ̀fù ti All Africa Challenge Trophy (AACT), ọdún 2026 fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti yóò wáyé ní
IBB International Golf and Country Club ní ìlú Abuja.

 

Alága àjọ NSC, Shehu Dikko, sọ òtítọ ọ̀rọ̀ yíì nìgbà ti o gbalejo ikọ̀ Ladies Golf Association of Nigeria (LGAN) ní ọjó Etì ní Abuja, ti ààrẹ LGAN, Lami Ahmed ṣáájú ikọ̀ náà.

Ìdíje AACT ọdún 2026 ní yóò máa wáyé láti ọjó kinni oṣù Kọkànlá sì ọjọ Keje oṣù Kọkànlá, nibi ti ìgbàgbọ́ ti wà pé Ọgbọ̀n orílẹ-èdè ní yóò kópa. ní ilu Abuja.

 

Orílẹ-èdè Nàìjíríà gbàlejò idije náà ní ọdún 1996 ní Ikoyi Club 1938, Lagos, àti ní odun 2010 ni IBB International Golf and Country Club, ìlú Abuja. Ìdíje ọdún yìí yóò jẹ ìgbà kẹta ti orílẹ-èdè Naijiria yóò gbalejò rẹ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Comments are closed.

button