Ààrẹ ẹgbẹ́ awon oloja lorile-ede Naijiria, Alhaji Mustafa Ahmadu, ti rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti mu iṣẹ́ àgbẹ̀ lokúnkundun, kí wọ́n sì padà sẹ́nu iṣẹ́ àgbẹ̀, nitori pé kí orílẹ̀-èdè kankan to le bo ara re yo, tabi ṣaṣeyọri lori pipese ounje lopoyanturu, awọn ara ilu ati awọn aladani gbọdọ ni ifowosowopo pelu agbekalẹ awọn eto ijoba.
Ahmadu sọ eyi di mimọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ alaṣẹ tuntun ti agbegbe Guusu-Iwọ-oorun ti NARPPMMAN, ni ile-itura Lafia,ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Gege bi o ti so,won ni lati tunbo seto iresi daradara, nitoripe bi o se n gbowo lori je nkan ti o nko gbogbo eniyan lominu , nitorinaa gbogbo awọn ọmọ Naijiria ni lati pada si oko lati ṣe iṣẹ agbe.
Leave a Reply