Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Ṣèlérí Láti Dá àwọn ilé-iṣẹ́ àti Àjọ Tuntun Sílẹ̀ Fún Ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Ọyọ́

80

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí ìdásílẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ àti àjọ tuntun fún ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gómìnà ṣe ìlérí yìí níbi ìpàdé ìjíròrò eléyìí tó ṣe ọkan lára àmì ayẹyẹ Àádọ́ta ọdún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ètò tó wáyé ni gbàngàn ‘International Conference Centre’ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fafiti Ìbàdàn.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Makinde tẹnu mọ́ pé ìdí pàtàkì ti ìṣèjọba rẹ̀ fi dá àwọn àjọ tuntun sílẹ̀ ni láti mú ìdàgbàsókè ti kò ṣeé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn dé bá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìṣèjọba òun tí n gbaradi fún àwọn àlàkalẹ̀ ètò ti yóò mú ìdàgbàsókè dé bá Ìpínlẹ̀ náà ju ọdún 2027 lọ.

Akọ̀wé Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Aṣòfin George Akume, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí Gómìnà Makinde àti gbogbo àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọyọ́ kú ayẹyẹ àádọ́ta ọdún ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ náà.
Ó tún Io àsìkò náà láti gbé óríyìn fún àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọyọ́ fún èmí ìtẹ́lọ́rùn, ó sì gbàdúrà kí Ìpínlẹ̀ Ọyọ́ máa tẹ̀síwájú láti ipá dé ipá.

Nínú ọ̀rọ̀ pàtàkì rẹ̀, Alákóso Àgbà Ilé iṣẹ́ African Center for Shared Development Capacity Building, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olu Ajakaiye, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí to sọ pé “Ayeye Ogún-ìbí, Líla ipa fun Ọjọ́ Òní, àti Ìwòye Ọjọ́-Ọla,” lu Gómìnà Makinde lọgọ ẹnu fún bí ó ṣe ṣe àgbédìde ìlànà fún ìdàgbàsókè Ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn àtijọ́, nípasẹ ìlànà tó ṣe é fojú rí, tó sì ní àkọsílẹ̀ rere.

Bákan náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ajakaiye ke sí Gómìnà Makinde láti ṣe atilẹyin fún àwọn ilé iṣẹ́ àti àjọ ti ìṣèjọba rẹ̀ dà sílẹ̀, kò sì ṣe ohun gbogbo láti mú òpin dé bá ìwà jàndùkú ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, Alága ìgbìmọ̀ ayẹyẹ Àádọ́ta ọdún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Saheed Akinade-Fijabi ṣàlàyé pé àkòrí ayẹyẹ Àádọ́ta ọdún náà wà ní ìbámu pẹ̀lú bi ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú àkókò yìi se rí.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button