Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Fún Ètò Ọmọnìyàn Wàásù Ìṣọ̀kan Fún Àwon Alẹ́nu-lọ́rọ̀ Àríwá Plateau

185

Mínísítà fún Ètò Ọmọnìyàn àti Ìdínkù Òṣì ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Dókítà Bernard Doro, tí pé ìpàdé gbogbogbò àwọn alẹ́nu-lọ́rọ̀ agbègbè Àríwá ní Ìpínlẹ̀ Plateau. O ń pé fún ìṣọ̀kan, ìdàgbàsókè ìkópa nínú ètò òṣèlú àti àlàáfíà bí ẹgbẹ́ òṣèlú ‘All Progressives Congress (APC)’ ṣé ń ṣé ìforúkọsílẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣáájú ìdìbò tó mbọ̀ àti ọjọ́ iwájú.

‎ Ìpàdé náà, tó wáyé ní Jos, Olú-ìlú ìpínlẹ̀ náà, ṣe àkójọ àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn àgbà ìlú ati awọn tó wà nípò kan tàbí èkejì nínú òṣèlú ní agbègbè Àríwá tí Ìpínlẹ̀ Plateau lapapọ.

‎Nigba to n ba awọn olukopa sọrọ, Dokita Doro sọ pe èròngbà òún ní lati ba awọn olugbe sọ̀rọ̀ kí wọ́n rẹ̀ láàrín ará wọn ni Agbègbè Aṣojú ti Àríwá Plateau, pàápàá láti forukọsilẹ ninu iforukọsilẹ ẹgbẹ APC ti nlọ lọwọ.

Comments are closed.

button