Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ti ṣe àbẹ̀wò sí Gbong Gwom ní Jos àti Alága ìgbìmọ̀ àwọn Olóyè tí ó tún jẹ́ Emir ìpínlẹ̀ Plateau, Olóyè, Jacob Gyang Buba.
Igbakeji Aarẹ wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ni ifarada ati iṣọkan lasiko to ṣe abẹwo naa, wipe orilẹ-ede ni anfaani lati jẹ ọkan ninu awọn to dara julọ lagbaye ti awọn ara ilu ba gbe papọ pelu irọrun.

Nigba ti o n sọrọ lasiko igbawọle gbogbogboo ti Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang ati awọn oloṣelu janjan jankan sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Shettima gboriyin fun awọn lọba lọba fun ipa ti wọn n ko lawujọ.

Igbakeji Aarẹ tun wa yin fun ajọṣepọ to danmọran laarin Alaga ẹgbẹ APC lapapọ, Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda, ati Gomina Mutfwang, ti o si n ṣapejuwe ajọṣepọ oṣelu wọn bii ilọsiwaju lọna to tọ fun ipinlẹ Plateau.
Shettima wa ni o da oun loju pe ifọwọwẹwọ naa yoo tun ipo ipinlẹ naa ṣe, tunbọ fif alaafia mulẹ, ati ti yoo si ko ipa irọrun ba orilẹ-ede.

Igbakeji Aarẹ wa dupẹ lọwọ ijọba ati awọn eniyan ipinlẹ Plateau fun bi wọn ṣe gba oun wọle pẹlu ifẹ.
Gomina Mutfwang, niinu ọrọ rẹ, wa yin ibaraeniṣepọ iṣiṣẹ to fesẹ mulẹ laarin Aarẹ Bola Tinubu ati Igbakeji Aarẹ Shettima, ti o si n sọ pe gbogbo eniyan orile-ede ni yoo maa janfaani rẹ.