Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà, Turkiye buwọ́lu ìwé àdéhùn MoUs ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn án

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

92

Adarí Nàìjíríà, Ààrẹ Bola Tinubu pẹ̀lú ẹǹikejì rẹ̀ ti Turkiye, Recep Tayyip Erdogan, ti wà níbi ìbuwọ́lù ìwé àdéhùn ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn án tó kó ìdáàbòbò àti ààbò, kárà kátà àti ìdókòwò, iná, àti ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé mọ́ra.

Aarẹ Tinubu bẹrẹ ibẹwo orilẹ-ede rẹ si  Türkiye lọjọ Iṣẹgun lẹyin ayẹyẹ ikini kaabọ ti wọn ṣe fun ni Ankara, leyi to sami ibẹrẹ ajọṣepọ to lakọsilẹ laarin orilẹ-ede mejeeji.

Ajọfẹnuko yii ti wọn buwọlu yii ni iwe adehun lori ifọwọsowọpọ lori imuṣe laarin awọn ti n gbe loke okun ati ile iṣẹ Aarẹ Turks lorilẹ -ede miran ati awọn agbegbe to so mọ ile iṣẹ ijọba apapọ Türkiye ti n risi ọrọ Aṣa ati Ajọ ti n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria ti n gbe loke ọkun.

Ibuwọlu iwe adehun yii naa tun waye laarin Türkiye ati ijọba orilẹ-ede Naijiria ni abala ohun igberoyin jade ati ibaraẹnisọrọ.

Ibuwọlu iwe adehun ọhun tun ko ọrọ ifọwọsowọpọ ni abala ile ẹkọ giga mọra.

Comments are closed.

button