Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ NLNG Ṣe Ìdánilékòó Fún Àwọn Oníròyìn Méjìlèlọ́gbọ̀n Nípa Ìròyìn Dígítà.

22

Ẹgbẹ́ ti wọn n pé ni NLNG ti túbọ̀ ṣe atilẹyin fún àwọn ẹgbẹ́ Oníròyìn Látàrí bi wọn ṣe ṣe ìdanilékọ̀ọ́ fún àwọn oníròyìn mejilelọgbọn nípa imọ to Peregedé jùlọ nipa dígítà.

Ìdanilékọ̀ọ́ náà jè ọlọjọ méta ni ìlu Abuja Labe ẹgbẹ́ NLNG ti wọn pé Àkòrí  re ni Tun ìtàn rẹ kọ.

Nìgbà ti ó ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ níbi ìdanilékọ̀ọ́ náà , ọgá fún ìdàgbàsókè Labe ẹgbẹ́ NLNG, Dókítà Sophia Shortfall so wí pè ìdanilékọ̀ọ́ náà fún àwọn oníròyìn láti tèsíwájú nínú ìṣe wọn , ki wọn sì ni imò to yé koro nibi gbogbo lágbayé.

Ó ṣe àpèjúwe atilẹyin ẹgbẹ́ NLNG fún àwọn oníròyìn ati fífún àwọn ènìyàn ni ààmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́bí ohun ìwúrí púpọ, o ni èyí yóó mu iṣọkan ati ifẹ hàn láàrin àwọn Oníròyìn.

Bákanáà àwọn oníròyìn to kópa kakakiri Orílè-èdè Nàìjíríà dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ náà fún akitiyan wọn  ni àwọn yóò ló ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ ti wọn ri gbà lásìkò ìdanilékọ̀ọ́ náà, wọn ṣe ìlérí láti mu gbogbo ìmọ̀ náà wá sí enu isẹ wọn kakakiri.

Comments are closed.

button