Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Jẹ̀jẹ́ Àtìlẹ́yìn Fún Zambia

140

 

Ìgbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí Kashim Shettima ti sọ pé ilẹ̀ olominira Zambia àti Naijiria ti jọ wà tipẹ́ nípa ọlörẹ́sọ̀rẹ́, àti pé ìjọba ààrẹ Bola Tinubu ti ṣetan láti tun jẹ kí àjosépọ̀ wọn tubọ máa tèsíwájú.

Ìgbákejì ààrẹ sọ èyí ní ọjọ́ Ọjóbọ̀ nígbà ti o gba àwọn alejo pàtàkì, Dókítà Samuel Miambo láti ọdọ ààrẹ Hakainde Hichilema ti orílẹ̀-èdè Zambia lálejò ní gbọ̀ngàn ààrẹ ní Abuja.

Ìgbákejì ààrẹ Shettima fi dá àwọn ìkọ náà lójú pé orílè-èdè Nàìjíríà yóò máa tèsíwájú ninu atilẹyin rẹ̀ pẹ̀lú orílè-èdè Zambia àti ènìyàn rẹ nípasẹ̀ ṣíṣe àkànṣe ètò ti yóò ràn ìgbé ayé àti ìgbésí ayé àwọn ènìyàn orílè-èdè méjèjì lọ́wọ́.

Lára àwọn ènìyàn tó ṣáájú ìkọ náà wà sí òdo igbakeji ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà láti ri, Kọmísọ́nà àgbà ilẹ̀ Zambia si orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Àm̀básédọ̀ George Imbuwa, Oludamọran pàtàkì sì ààrẹ orílẹ̀-èdè Zambia ọ̀gbẹ́ni Manfred Ndonuie àti ìyáàfin Elita Mwambazi.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button