Ẹgbẹ́ Akọ̀ròyìn Obínrin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NAWOJ) ẹká tí Ìpínlẹ̀ Ogun tí fí ìbànújẹ ọkàn wọ́n hàn lórí ikú ọkán lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọ́n, Iyaafin Bukola Agbakaizu.
Ìyáfín Agbakaizu, ẹni ọdún méjìlèlàádọta, tún jẹ́ ọkan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ oníròyìn (Nigeria Union of Journalists, NUJ), tí Ìpínlẹ̀ Ogun àti òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ tẹlifísàn ìpínlẹ̀ Ogun (OGTV). Wọ́n sọ pé o ṣubu lọ́jọ́ Àjé tó kọjá yí lásìkò tó ń múra fún iṣẹ́ tí ọsán, tí wọ́n sí gbìyànjú sáré gbé lọ sí ilé-ìwòsàn tí ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Idi-Aba, Abeokuta, níbí tí wọ́n tí sọ pé o tí kú.
Nínú àlàyé ìtùnú tí Alága NAWOJ tí Ogun, Sekinat Salam fọwọ́sí, ikú Ìyáfín Agbakaizu jẹ́ kayefi sí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́. O sí gbá làdúrà pé kí Oluwa tẹ́ sí afẹ́fẹ́ iré.
Comments are closed.