Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà gbóríyìn fún Ààrẹ bí ó se ka àwọn iṣẹ́ àkànṣe tí yóò ṣíṣọ lójú rẹ̀ sílẹ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

85

Mínístà Nàìjíríà fún olú ìlú (FCT), Ọ̀gbẹ́ni Nyesom Wike, ti ṣàlàyé pé Abuja ti rí àyípadà tó lápẹẹrẹ lábẹ́ ìṣàkóso Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

Míníst sọ eyi di mimọ lasiko abẹwo ibojuto iṣe Akanṣe opopona Gishiri ati Wassa ni ọjọ Abamẹta.

Wike wa sọ pe ijọba Tinubu ti mu Atunṣe Ireti ati idunnu ba awọn olugbe nipasẹ iṣadari to nipa ati pipese awọn ohun amuludun to ṣe pataki.

O tun wa ṣalaye pe pẹlu atilẹyin ti n wa lati ọdọ Aarẹ, awọn ọpọlọpọ iṣẹ Akanṣe amayedẹrun pataki ni o ti pari ti wọn yoo si ṣiṣọ loju wọn lati fi sami ọdun keji Aarẹ lori oye.

ohun ti o maa n munu wa dun ni, nigbati inu awọn eniyan ba dun, nitori pe eyi ni yoo jẹ ki a mọ pe  a n ṣiṣẹ fun awọn eniyan,” Wike sọ bayii.

Gegẹ bi Minisita ṣe sọ, “Mo ti sọ tẹlẹ, iṣejọba niṣoro pataki. Ti ijọba to tọ ba wa, awọn eniyan yoo janfaani ninu ẹ, Aarẹ ti fihan pe ohun ti ṣetan lati yipada. O ti ṣetan lati mu inu awọn eniyan dun ati pe lododo, Agbekalẹ Atunṣe Ireti rẹ n ṣiṣẹ.”

Minisita wa gboriyin fun ile iṣẹ China ti n ṣe ọna naa, CGC, bi o ṣe mu ipinnu rẹ wa si imuṣẹ nipa pe oun yoo pari awọn ọna naa lasiko ti Aarẹ yoo ṣe Ajọdun Ayẹyẹ rẹ, ti o si sọ pe OSEX Keji si ipinya opopona Wassa ati agbegbe Gishiri ti pari fun ifilọlẹ.

Comments are closed.

button