Mínísítà fún ètò Ẹ̀kọ́, Dókítà Maruf Alausa, tí kéde ìdádúró ọdún márún lórí àjọṣepọ̀ ètò ẹ̀kọ́ lókè òkun látí ṣé ìdàgbàsókè àlàáfíà fún àwọn ọmọ Ilé-ìwé.
Nígbàtí o n sọrọ lẹ́yìn àtúnyẹwò nlá tí àwọn ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn ìlú òkèèrè, Dókítà Alausa sọ pé gbogbo ìmọ ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè yìí ń lọ́ fún loke òkun, ló tí wà ní àwọn ilé-ìwé wá ní Orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà.
Nígbàtí o n sàlàyé lórí ìpinnu náà nínú ọrọ tí Olùdarí Àwọn ìròyìn tí ilé-iṣẹ́ náà, Boriowo Folashade, Mínísítà náà tẹnumọ pé l’àkókò tí ìdádúró náà ṣé ìwúrí fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí orílẹ̀-èdè yìí, kó ṣé idiwọ fún àwọn obi láti ṣé àtìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ wọ́n látí kàwé ní òkè òkun.
Comments are closed.