Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Ghana, John Mahama ti dá àdájọ́ àgbà, Gertrude Torkornoo dúró lẹ́nu iṣẹ́ fún àkókò díẹ̀ tí wọn yóò fi se ìwádìí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án
Èyí ni ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ti wọn yóò dá adájọ́ àgbà dúró lẹ́nu iṣẹ́ ní Orílẹ̀-èdè náà. Ìgbésẹ̀ náà wáyé látàrí onírúurú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án èyí tí ó pè fún ìyọnípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà. Lára àwọn ẹ̀sùn náà ní àìkójú-òsùwọ̀n àti ìwà àjẹbánu
Arábìnrin Torkornoo, ni ó jẹ́ Obìnrin ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí ó jẹ́ Adájọ́ Àgbà ní Orílẹ̀-èdè Ghana ní Ọdún 2023, nígbà tí Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí Nana Akufo-Addo yàn-án sípò, ni kò ì tí ì sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà