Àjíǹde: Adarí ilé, Igbákejì rọ àwọn kírísítíẹ́nì láti kọ́ ìṣe kŕisítì
Eyitayó Fauziat Oyetunji
Adarí ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú, ọ̀gbẹ́ni Abbas Tajudeen àti igbákejì rẹ̀ Benjamin Kalu ti rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn kírísítí láti kọ́ ìṣe ìfaradà Jésù Kírísítì.
Wọn rọ awọn ọmọ Naijiria lati ni ifẹ ara wọn lai bikita ẹya, ẹsin, ati ọrọ aje awujọ ti wọn o baa jẹ.
Nigba ti o n ki awọn ọmọ lẹyin kirisiti lori abajalẹ asiko aawẹ, Adari ile wa gbadura pe ki ajọyọ ọdun Ajinde yii ko mu saa tuntun ifaramọ, ifẹ, ati otitọ.
Adari wa pe fun ifarada ẹsin ati irẹpọ laarin awọn ọmọ Naijiria, ti ijọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu si maa tẹ siwaju lati pese Agbekalẹ Atunṣe Ireti.
Ninu alaye kan lati ṣami ayẹyẹ ọdun Ajinde ọdun 2025, Kalu ṣalaye ẹkọ iṣaanu Kirisiti, iforijin, ati iṣoore, ti n si n rọ awọn ọmọ orilẹ-ede lati kọṣe awọn iwa daradara wọnyii.
Igbakeji Adari ile wa sọ pe kirisiti ṣafihan apẹẹrẹ aláìnímọtara-ẹni-nìkan ati ifaramọ,ti o si fi kun pe “His Ajijinde rẹ jẹ ami ireti ati irapada”.
Kalu naa tun wa rọ awọn eniyan lati gbadura fun iṣọkan, alaafia, ati ilọsiwaju Naijiria, ti o si ni oun ni ireti pe ijọba Bola Ahmed Tinubu yoo tẹ siwaju lati ṣiṣẹ fun ilọsiwaju orilẹ-ede lai kaarẹ ọkan.