Adarí ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú, Ọ̀gbẹ́ni Abbas Tajudeen àti Igbákejì Adarí, Ọ̀gbẹ́ni Benjamin Kalu, ti bẹnuàtẹ́ lu ìkọlù tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ̀ yìí ní agbègbè Ruwi, Manguna, Daffo, Josho àti Hurti ní ìjọba ìbílẹ́ Bokkos ti ìpínlẹ̀ Plateau.
Iroyin sọ pe ikọlu naa gba ẹmi to pọ, pẹlu ọpọlọpọ ifarapa, paapaa julọ awọn ọmọde ati obinrin.
O bi Adari ile ninu ti o si sọ pe ko si ọgbọn kan kan nibẹ ti o si burujai.
Adarí ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú Abbas banujẹ lori ipaniyan naa, ifarapa, ati ipadanu dukia,ti o si ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bii “ohun ti o lagbara.”
Nigba ti o n kẹdun pẹlu awọn ẹbi olufaragba, Adari wa rọ awọn eleto aabo lati mu awọn ọdaran naa ki wọn o si da ẹjọ to ba yẹ fun wọn, o wa kilọ pe aima da ẹjọ to tọ fun wọn ko ni lẹyin to dara.
Adarí wa kẹdun pẹlu awọn eniyan ati ijọba ipinlẹ Plateau, ti o si gbadura ki ọlọrun gba abọ awọn to ti ku, ki ọlọrun o si rọ awọn ẹbi wọn loju.
Igbákejì Adarí ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú, Ọgbẹni Benjamin Okezie Kalu, naa bẹnuatẹ ipaniyan naa bakannaa.