Take a fresh look at your lifestyle.

Kẹ́dùn Ikú Èèkàn Nínú Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP, Adeojo

7

*
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kẹ́dùn ikú Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP to tún jẹ́ Seriki Mùsùlùmí Ilẹ̀ Yorùbá nígbà ayé rẹ̀, Alhaji Yekini Adeojo.

Makinde, ẹni tó fi ikú olóògbé Adeojo wé ìkẹhìn sáà òṣèlú tó lógo lo ti ránṣẹ ìbánikẹ́dùn sí ìdílé Adeojo, tó sì gbàdúrà kí Ọlọrun fún ìdílé náà ni okun láti gbà ikú olóògbé náà mọra.

Gómìnà tún ránṣẹ ìbánikẹ́dùn sí gbogbo ẹgbẹ òṣèlú PDP ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nígbà tó ṣàlàyé pé ikú rẹ̀ yóò fi àlàfo sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orile ede Nàìjíríà látàrí ipa rere tí olóògbé náà kò nígbà ayé rẹ̀.

Alahji Yekini Adeojo lo dágbére fún ayé yìí ni owurọ ọjọ kẹrin oṣù kẹrin, ọdún 2025.

Gómìnà wá gbàdúrà kí Allah fi Alujana onídẹ̀ra kẹ ẹ.

Abiola Olowe,
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button