Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òsèlú APC Se Ìpolongo Ìtanijí Ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi

109

Ẹgbẹ́ Òsèlú APC ti bẹ̀rẹ̀ ìwọlé ní ojúlé sí ojúlé láti ta àwọn alátìlẹyìn, ọmọ ẹgbẹ́ náà jí jákè-jádò ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlá tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi

 

Alága ẹgbẹ́ náà ti Ìpínlẹ̀ Ebonyi, Stanley Okoroemegha ni ó síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọ́ọ́fìsì ẹgbẹ́ náà, èyí tí ó wà ní Abakaliki, olú ìlú Ìpínlẹ̀ náà

 

Emegha salaye pé ìtanijí náà se pàtàkì nítorí pé lẹ́yìn ìpolongo ìdìbò tí ó kọjá, ẹgbẹ́ náà kò ì tí ì se àbẹ̀wò sí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ní ibùgbé wọn

 

Ó wá lo ànfààní náà láti se àfọ̀mọ̀ awuyewuye tí ó ń lọ wípé wàhálà wà láàrin gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi, Francis Nwifuru ati Mínísítà Fún Àkànṣe Iṣẹ́, David Umahi

 

 

Comments are closed.

button