Take a fresh look at your lifestyle.

16

Ààrẹ Nàìjíríà Kéde Ìlú Kò Fararọ Ní Ìpínlẹ̀ Rivers

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti kéde ìlú kò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kẹta ọdún 2025 nígbà tí ó ń bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀.

Nípa ìkéde yìí, Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Ọ̀gbẹ́ni Siminalayi Fubara, ìgbákejì rẹ̀ , ìyáàfin Ngozi Odu àti gbogbo àwọn ti wọ́n dìbò fún sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Rivers ni wọ́n ní láti se gààyà díẹ̀ fún oṣù mẹ́fà .

Ààrẹ sọ pé, pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ipinlẹ náà kòsí ààrẹ gidi kan ti yóò fọwọ́ lẹ́rán kó máa wòran ṣùgbọ́n ki irú ààrẹ bẹ́ẹ̀ tètè wá ojútùú sí rògbòdìyàn to n sẹlẹ̀ níbẹ̀ bi òfin ti làá kalẹ̀ kí àlàáfíà, ìjọba rere, ati ààbò tó péye sí jọba ni kíámọ́sá.

Ààrẹ Tinubu sọ ìdí tó fi kéde ìlú ò fara rọ bíi; fífọ́ ọ̀pá epo láti ọwọ́ àwọn adìhámọ́ra ọmọ kọ́mọ ọmọ ogun tí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà kòsí lee dáwọn lọ́wọ́ kọ́. Adarí orílẹ̀-èdè yìí wa kéde ajagun fẹ̀yìntì – Vice Admiral Ibokette Ibas bí adarí tuntun ìpínlẹ̀ náà, Ó sí tun sọ pé ìkéde ìlú ò fara rọ náà kó di iṣẹ àwọn ẹ̀ka ti olùdájọ́ ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ láti se isẹ́ wọn, wọn yóò máa se isẹ́ wọn bi òfin ti làá kalẹ̀.

Alábójútó tuntun ìpínlẹ̀ kòní se òfin tuntun sùgbọ́n ó ní ànfààní láti ṣe àwọn ètò ti yóò mu ki iṣẹ́ rẹ̀ seése sùgbọ́n ètò náà ni àjọ Federal Executive Council níláti kọ́kọ́ buwọ́lù tí ààrẹ náà yóò sí mọ̀ sí fún ipinlẹ náà. ” Ìrètí mi ni wípé ìgbésẹ̀ tó pan dandan yìí yóò mu ki àlàáfíà àti àṣẹ padà wá sí ìpínlẹ̀ Rivers… ààrẹ sọ eyi.

Ààrẹ Tinubu tun sọ pé ki àwọn agbófinró rí wípé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà wà ní àlàáfíà kí nǹkan kankan másì se ọ̀pá epo.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button