Take a fresh look at your lifestyle.

NAFDAC Ṣèlérí Látí Ṣé Àbójútó Òògùn Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Lekan Orenuga

264

Àjọ tí orílẹ̀-èdè fún Oúnjẹ àti Oògùn fún àbójútó àti ìṣàkóso (NAFDAC) sọ pé àwọn kó ní sinmi lórí ìṣẹ́ rẹ̀, nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti ṣàkóso lílo òògùn ní Nàìjíríà

‎ Olùdarí àgbà tí ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisola Adeyeye, ṣé ìkéde náà ní Ọjọ́rú, ní àpéjọ pàtàkì kán tí a pè ní ‘Ìpàdé pẹ̀lú àwọn Oníròyìn,’ tí Ẹká Ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ní Abuja.

‎ Èyí ló wáyé lẹ́yìn ìkọlù àjọ náà láìpẹ́ yí sí àwọn ọjà òògùn mẹta pàtàkì ní Abia, Anambra àti Ìpínlẹ̀ Èkó, níbití wọ́n tí gbá àwọn ayédèrú oògùn tó tó tiriliọnu kan náírà ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ilé-iṣẹ́ ààbò ìlú.

‎ Ọ̀jọ̀gbọ́n Adeyeye náà sàlàyé pé àwọn Gómìnà tí àwọn ìpínlẹ̀ tí ọrọ kán ní Olùdámọ̀ràn Ààbò tí Orílẹ̀-èdè tí kán sí ní àkọkọ́, atipe àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí àwọn ọjà mẹtẹẹta náà tún mọ̀ sí.

Comments are closed.

button