Take a fresh look at your lifestyle.

Abúgbàmù Kankan kò wáyé ní ilé ìfọpo Warri – NNPCL

Eyitayó Fauziat Oyetunji

145

Ilé iṣẹ́ tí ń rísí ọ̀rọ̀ epo ilẹ̀ lórílẹ̀-èdè (NNPC), ti tako ìròyìn abúgbàmù ní ilé iṣé ìfọpo Warri (WRPC), tí wọ́n sí ṣàlàyé pé àwọn àtúnṣe ètò tó máa ń wáyé lóórè kóòrè nílé iṣẹ́ náà ló ń lọ lọ́wọ́.

Alaye kan lati ile iṣẹ naa, NNPC sọ pe wọn tilẹ da awọn eto iṣẹ ni agbegbe kinni WRPC duro di ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kinni, 2025, lati faaye gba awọn iṣe pataki kan lori awọn ẹrọ iṣiṣẹ.

Gẹgẹ bi olori eto ibaraẹnisọrọ fun ile iṣẹ naa, Olufemi Soneye, ṣe sọ, itunṣe yii, ti o mọ́ awọn ẹrọ ti o niiṣe pẹlu awọn iṣẹ pataki, pa dandan lati ṣe fun  ipese awọn ohun elo pataki epo ilẹ bii epo mọto (AGO) ati kẹrosiini (Kero).

Bi ile iṣẹ NNPC ṣe sọ, itunṣe ile iṣẹ naa n tẹ siwaju bi wọn ṣe ti ṣọ silẹ, ti agbagbe kinni yoo si pada bẹrẹ iṣẹ ni aipẹ ọjọ.

Ṣugbọn pẹlu awọn eto to n lọ lọwọ yii, AGO ṣi n pese bi tatẹyinwa, ti bii ọkọ epo mẹjọ si n pin epo lojoojomọ lati bii ọjọ mọkanla sẹyin.

Comments are closed.

button