Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Orílè-èdè Nàìjíríà Mú ọjọ́ Ìsinmi Fún Ọdún Kérésìmesì Àti Ọdún Tuntun.

25

Ìjọba Orílè-èdè Nàìjíríà tí mú ọjọ́rú ọjọ́ karúnlelogun oṣù Kejìlá 2024 àti Ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kerindinlogbon gẹgẹ bí ọjọ ìsinmi fún odún Kérésìmesì.

Bákanáà ọjọ́ kini oṣù kínní ọdún 2025 fún isinmi ọdún Tuntun.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìlú Olubunmi Tunji -ojo ló sọ èyí di mímọ̀ ni orúkọ ìjọba àpapọ̀.

O wá fi àkókó náà kí gbogbo àwọn ọmọ Orílè-èdè Nàìjíríà ku ayẹyẹ ọdún kérésìmesì àti ọdún Tuntun.

Ó sí tún rò wọn láti sọra gidigidi lásìkò irọ́pòpọ̀ ọdún.

Ọ̀gbẹni Tunji -ojo tún fi àsìkò náà sàlàyé ìdí tí wọn fi se ayẹyẹ ọdún kérésìmesì, o ní láti wà nínú irẹpọ, àlàáfíà, ìsọkan káàkiri àgbáyé, agbègbè, ìlú àti láàrin ẹbí.

Ó wá pé àwọn ènìyàn láti wà nínú iṣọkan, àlàáfíà, irẹpọ àti ìfẹ fún Ìdàgbàsókè ìlú àti Orílè-èdè Nàìjíríà.

Comments are closed.

button