Ògbóìtarìgì afẹ̀sẹ́kù bi òjò ni, Israel Adesanya ti gboriyin fún Francis Ngannou bi àkànṣẹ́ tó dára lẹyìn to ti lu Renan Ferreira bi ẹni lu bara ni ibi ija ti PFL Super .
Bi Ngannou ti padà sórí agbo ija ti
MMA ti PFL, ló ti fìtàn balẹ tó sì lu Ferreira ni a abala àkọkọ, eleyi mu ki o gbayi láàrin awọn akànsé nì àgbáyé.
Adesanya, sọ pé inú òún dùn jọjọ fún akànṣẹ́ Ngannou fún aseyege alailẹgbẹ náà lẹyìn ọpọlọpọ ìsòro ti ọmọ bíbí ìlú meji- Cameroonian-French ti la kọja ni àìpẹ; eléyìí yóò mú ki awon eniyan tubọ máa bọlá fún, wọn yóò sì tún máa bẹ̀rù rẹ̀ ni agbo ìjàkadì.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san