Olùrànlọwọ pàtàkì sí Ààrẹ lórí àwọn ilé-iṣẹ́ Kékèké àti Alábọ́dé (MSMEs) àtí idasilẹ iṣẹ́, Temitola Adekunle-Johnson, tí tún ṣé àfihàn ìpinnu Ààrẹ Bola Tinubu látí pèsè àwọn ilé-iṣẹ́ kékèké (MSMEs) ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Èyí tẹ̀lé ìfilọ́lẹ̀ tí Ìgbìmọ̀ ilé-iṣé Olókó-owó Kékèké (MSMEs) nípasẹ Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ ní Abuja ní ọjọ́ Ẹtì.
Adekunle-Johnson tó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ náà ní ilè ìjọba láìpẹ́ yìí lẹyìn ìfilọ́lẹ̀ náà, Ó tẹnu mọ́ pé Nàìjíríà tí ṣetán fún àwọn oníṣòwò nítorí náà, kí àwọn oludokoowo wà ṣòwò ní orílẹ̀-èdè náà.

Olùdarí àgbà tí àwọn olówó Kékèké àtí Alábọ́dé (SMEDAN), Ọ̀gbẹ́ni Charles Odii, tó tún bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ bó ṣé fí dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lójú pé Ìgbìmọ̀ túntún náà ní yóò ní aṣojú ní gbogbo ìpínlẹ̀ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀.
Leave a Reply