Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Búra Fún Àwọn Mínísítà Mẹ́ta Mìíràn

0 279

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí búra fún àwọn Mínísítà mẹ́ta tí àwọn ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ṣé àyẹwò wọ́n láìpẹ́ yìí.

Àwọn Mínísítà náà ní Dókítà Jamila Bio Ibrahim (Ìpínlẹ̀ Kwara) Ayodele Ọlawande (Ondo) àti Balarabe Abbas Lawal (Ìpínlẹ̀ Kaduna).

Àwọn Mínísítà túntún náà ní Ààrẹ Tinubu búra fún làkókò kànnà kí ìpàdé Ìgbìmọ̀ Àwọn Aláṣẹ Ìjọba Àpapọ̀ (FEC).

Dókítà Jamila Bio Ibrahim yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ètò àwọn ọdọ nígbà tí Ayodele Ọlawande (Ondo) yóò jẹ́ Mínísítà tí ìpínlẹ̀ fún àwọn ọdọ.

Balarabe Abbas Lawal ní láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún Àyíká.

Lẹyìn náà, Akọ̀wé sí Ìjọba àpapọ̀, George Akume kéde ikú Mínísítà àkọ́kọ́ tí Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè Naìjírìà, Oloye Mobolaji Ajose-Adeogun, tó jáde láyé ní ọjọ́ kínní oṣù Keje, ọdún yìí.

Ọdún 1976 ní ìjọba ológun Murtala Mohammed yàn an gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè, o sí ṣiṣẹ titi dì ọdún 1979.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button