EU yóò ná iye owo ́tó ju bílíọ́nù méjìlé-lọ́gbọ̀n Náírà lọ lórí ẹ̀kọ́, ìrónilágbára àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àjọ Ìṣọ̀kan Yúróópù (EU) yóò ná iye owo ́tó ju bílíọ́nù méjìlé-lọ́gbọ̀n Náírà lọ lórí ẹ̀kọ́ àti ìrónilágbára àwọn ọ̀dọ́ ní Àríwá-iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, pẹ̀lú ìfojúsí lórí àwọn ọmọbìnrin ní àwọn ìgbèríko àti abúlé.
Aṣoju Ajọ Iṣọkan Yuroopu si Naijiria, Samuela Isopi sọ eyi di mimọ lasiko ipe apọnle Minisita ipinlẹ fun eto Ẹkọ, ọjọgbọn Mamman Tahir ní Abuja, Naijiria.
O sọ pe wọn yoo ṣe ifilọlẹ eto naa ti yoo kan ipinlẹ Kano, Jigawa ati Sokoto ní ọjọ́ kọkandin-logun, oṣu kẹwaa, ati pe wọn ṣagbekalẹ eto naa lati ran ijọba Naijiria ni gbogbo ipele lọwọ ni abala eto ẹkọ nipasẹ fifi idi ilana ati imuṣẹ mulẹ, ati iṣatunṣe eto iṣakoso ọrọ lori ẹ̀kọ́ (EMIS).
Leave a Reply