Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Yan Àwọn Àgbà Àti Ìgbìmọ̀ Olùdámọ̀ràn

0 175

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti yan àwọn ìgbìmọ̀ àgbààgbà àti Olùdámọ̀ràn fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gẹ́gẹ́ bíi àtẹ̀jáde tí Olórí òṣìṣẹ́ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Otunba Segun Ogunsuyi fi ọwọ́ sí, ẹní to ti fi ìgbà kan ti jẹ Olórí òṣìṣẹ́ fún Gómìnà Adebayọ Slao-Akala, Saka Balogun ni Gómìnà fi ṣe Alága Ìgbìmọ̀ Àwọn Àgbààgbà, nígbà tí Alàgbà Wole Oyelese sí jẹ́ Alága ìgbìmọ̀ náà pẹ̀lú

Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ yòókù ní: Igbakeji Gomina tẹ̀lérí, Hameed Gbadamosi; Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ̀lérí, Alaja Mutiat Ladoja; Olóyè Jacob Aseyoro; Olóyè Sunday Ogunlade; Ambassador Ronke Adegoke; Olóyè Nureni Akanbi àti Olóyè Ademola Eyinade.

Bákan náà, Olórí òṣìṣẹ́ sọ siwaju nínú àtẹ̀jáde náà pé Oloye Bolaji Ayotunde ni yóò jẹ́ Alága Ìgbìmọ̀ Olùdámọ̀ràn.

Àwọn ìgbìmọ̀ Olùdámọ̀ràn yòókù ní: Olori Ile Igbimọ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ̀lérí, Aṣòfin Monsurat Sunmoni; Asofin Hoṣea Agboola; Aṣòfin Gbénga Babalola; Amofin Michael Lana to díje du ipò Gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú SDP; Amofin; Babatunde Oduyoye àti Aṣòfin Kamarudeen Adedibu.

Àtẹ̀jáde náà tún ṣàlàyé siwaju pé àwọn igbimọ oludamọran yòókù ni Gómìnà yóò kéde wọn laipẹ.

Nígbà tó n kí àwọn igbimọ náà, Gómìnà gbà wọn níyànjú láti ṣe ojúṣe wọn nínú itesiwajui ìdàgbàsókè Ipinlẹ Oyo àti àlàkalẹ̀ fún Ìdàgbàsókè ọlọjọ pipẹ.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button