Ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Anambra ti fi ìdí Ìyànsípò ọ́nárébù Beverly Ikpeazu-Nkemdiche àti Ọ̀gbẹ́ni Izuchukwu Okafor múlẹ gẹ́gẹ́ bi Kọmísọ́nà ní ìpínlẹ̀ náà.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ti Gómìnà Chukwuma Soludo ti fọwọ́ sí látàrí àbọ̀ ìròyìn ti kọmití tó wà fún àyẹ̀wò fínífíní àti ọ̀rọ̀ nípa ìdìbò, láti ọwọ́ alága awon kọmiti ati igbakeji Abenugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ọ́nárébù Chukwuma Okoye ti fi lédè pé wọ́n kún oju òṣùwọ̀n bíi Komisọ́na ìpínlẹ̀ Anambra.
Abenugan ilé ìgbìmọ̀ asyofin, onyarebu
Somtochukwu Udeze kàá síta gbígba wọ́n fún iṣẹ́ náà, àwọn amòfin sì gbà àbá náà wọlé nípa ìdìbò ohùn.
Nígbà ti wọ́n ń dúpẹ ẹ́, ọ́nárébù Nkemdiche tó ti jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tẹylẹ̀ tó sojú fún agbègbè gúsù Onitsha Kejì dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé fún Ìyànsípò wọn, ó wá jẹ̀jẹ́ pe wọn yóò sìn ìpínlẹ̀ náà daradara, wọn yóò sì gbárùkù ti gbogbo àlá Gómìnà Soludo láti jẹ́ kó wà sí ìmúsẹ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply