Ìjọba Orílẹ̀-èdè Scotland sọ pé àwọn ti gbà láti jọ̀wọ́ arákùnrin ọmọ ilẹ̀ Ameriika ti wọn fẹ̀sùn ìfipá-bá-ni-lò-pọ̀ kàn, tó tún purọ́ pé òun ti kú láti wá jẹ́jọ́ nílé.
Àwọn afẹ̀sùnkanni ará Amẹ́ríkà sọ pé orúkọ ọ̀gbẹni náà ni Nicholas Rossi, pẹ̀lú ẹ̀sùn ìfipá-bá-ni-lò-pọ̀ ní ilu Utah, sá kúrò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti bọ lọ́wọ́ mímú lọ sí ilé ẹjọ́, ó tún díbọ́n pé òun ti kú ní ọdún 2020 láti sòro fún àwọn agbófinró láti gbamú.
Rossi ni wọ́n kọkọ gbámú ni oṣù Kẹwàá Ọdún 2021 lẹ́yìn tó wọ ilé ìwòsàn ní ìlú
Glasgow pé òun ti ní àrùn COVID-19.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply