Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú ṣàjọyọ̀ fún Nàìjíríà ní ọdún mẹ́tàlé-lọ́gọ́ta

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 259

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin ti ṣàjọyọ̀ fún Nàìjíríà bí ó ṣe sàmì  ọdún mẹ́tàlé-lọ́gọ́ta òmìnira.

Aṣoju Julius Ihonbvere wa gbe Igbesẹ kan lẹyin Iṣami yii, o ni Naijiria ti la aimọye ipeninija kọja ti wọn si ni lati ṣajọyọ rẹ.

Nigba ti o wa n ki awọn ọmọ Naijiria ku oriire, o wa rọ awọn oloṣelu ati adari lapapọ lati fọwọsowọpọ ki Naijiria le jẹ ibugbe to dara julọ lati gbe fun gbogbo eniyan.

Igbakeji adari ile, Asoju Benjamin Kalu lo kọkọ sọrọ ki awọn miiran orisiriṣi naa to wa maa sọrọ nipa Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, Aṣofin Sada Soli, wa rọ ijọba lati koju ailaabo lorilẹ-ede.

O ni gbogbo isọri lorilẹ-ede ni on koju ọran kan tabi omiran.

Fun adari awọn ti ko pọ ni ile, Aṣoju Kingsley Chinda, ni ile igbimọ asofin ni lati din ọrọ ti wọn n sọ ku, ki wọn si mu iṣe ṣe.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button