Aṣòfin gbóríyìn fún ààrẹ Tinubu lórí ìpèsè àfikún owó iṣé fúngbà díẹ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asojú ṣòfin kan, Dókítà Ahmed Aluko ti gbóríyìn fún ìjọba Nàìjíríà fún bí ó ṣe fi ẹgbẹ̀rún márùnlé-lọ́gbọ̀n Náírà kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fún oṣù mẹ́fà.
Aṣofin ti n ṣoju iwọ oorun Ilorin/Gusu agbegbe ijọba apapọ ni ile igbimọ asoju lo ṣe igboriyin yii ni Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara , Ariwa Aringbungbun Naijiria nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ lori ayẹyẹ ominira ọdun kẹtale-lọgọta Naijiria.
Bi o ṣe n gboriyin fun agbekalẹ yii, Aluko tun wa sọ pe ijọba le ṣe ju bẹyẹn lọ, kii ṣe fifi kun owo oṣu oṣiṣe ijọba nikan, bi ko ṣe wiwa atunṣe si awọn agbegbe pataki ti o le yanju ọrọ to wa nilẹ ati ti yoo si ko ipa pataki lori awọn ara ilu laijẹ oṣiṣẹ ijọba nikan.
Aluko tun wa gboṣuba fun akitiyan gomina ipinlẹ Kwara Abdulrahman AbdulRazaq, bi o ṣe jẹ ọkan lara awọn gomina to kọkọ mu sisan ẹgbẹrun mẹwaa fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ ati awọn ti wọn ti fẹyinti lenu iṣẹ wa si imuṣẹ.
Aluko wa rọ awọn ẹgbẹ oṣisẹ lati ni suuru pelu ijọba ti o si tun gba ijọba Naijiria naa nimọran pe ki wọn tunbọ mu igbe aye ni itumọ si awọn ọmọ Naijiria.
Leave a Reply