Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀gá àgbà UN pè fún àtúnṣe tó dánmọ́rán fún àlàáfíà, ní ṣíṣàyájọ́ káríayé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 221

Akọ̀wé gbogbogbòò ti Àjọ Ìṣọ̀kan, Antonio Guterres, ti kéde “kọ́, wá ìdúróṣinṣin àlàáfíà fún gbogbo ènìyàn” jákèjádò àgbáyé.

O pe ipe yii ninu alaye kan ti o fi sọri Ayajọ Kariaye fun Alaafia ọdun 2023, ti o si sọ pe awọn eniyan ati ibugbe wa wa ninu laasigbo,” ti o si n pe akiyesi si ipa to lagbara ti ko ṣẹlẹ ri ti n koju ọmọniyan – latorii ede aiyede, iṣinipo pada, iyipada oju ọjọ, aise daradara lori ẹtọ ọmọniyan sí aidọgba

 “Alaafia kii ṣe erongba pataki nikan fun ọmọniyan. Alaafia pa dandan lati ni,”  Guterres sọ bayii, oun pẹlu aarẹ ile igbimọ gbogbogboo, Dennis Francis, ni wọn ṣadari ayẹyẹ Agogo Alaafia ati idakẹ jẹẹ iṣẹju kan loni ni Ọgba Ajọ Isọkan Japan lati ṣayajọ Kariaye.

Ayajọ Kariaye Fun Alaafia, maa n waye ni ọjọ kọkanle-logun, oṣu kẹsan an lọdọọdun, wọn fori ọjọ naa sọ ọjọ ti ko ní ipá ati ifopinsi ìjà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button