Take a fresh look at your lifestyle.

Okọ̀ Òfúrufú Russia Tó Lulẹ̀: Ọ̀gá Àwọn Wagner, Prigozhin Wà Lára Àwọn Tó Kú

0 188

 

Ọ̀gá àwọn Wagner, Yevgeny Prigozhin wà lára àwọn tó wà nínú ọkọ̀ òfúrufú tó laná tó já lulẹ̀ tó gbẹ̀mí gbogbo wọn, elétò ọkọ̀ òfúrufú Russia sọ èyí.

Ọkọ̀ òfúrufú náà ń lọ láti capital sí St Petersburg, ó sì gbé ènìyàn méje àti òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú mẹ́ta.

Prigozhin ló ṣáájú ikọ̀ alátakò sí ìjọba sí ikọ̀ ọmọ ogun Russia ní oṣù kẹfà tí ìlépa wọn sì já sí òfo.

Ìròyìn láti Grey Zone sọ pé olùgbé abúlé kan gbọ́ ariwo nǹkan méjì kí ó tó já lulẹ̀, ó tún rí oruru tó ń jáde. Ìròyìn Tass ròó ní tirẹ̀ pé, ọkọ̀ òfúrufú kan gbaná lẹyìn tó lulẹ̀ tán, wọ́n sì rí òkú èniyàn mẹ́rin.

Ọkọ̀ òfúrufú náà ti wà ní ojú òfúrufú fún bí wákàtí kan kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé, ó sọ èyí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button