Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Ológun Mali Àti Ààrẹ Russia Sọ̀rọ̀  Pọ̀ Lórí Ìdìtẹ̀gbàjọba Niger

0 201

Olórí Ológun orílẹ̀-èdè Mali, Assimi Goita, ti sọ pé òun ni ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú ààrẹ orílẹ̀-èdè Russia Vladimir Putin lórí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Niger.

Lórí òpó ẹrọ ayélujára, Goita sọ pé Putin sọ ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì ti àlàáfíà fi yẹ kó jọba ní agbegbe Sahel náà.

Àwọn orílẹ̀-èdè tó làḿì laaka ní àgbáyé n wòye pé orílẹ̀-èdè Niger lè fẹ́ rìn nípasẹ̀ orílẹ̀-ède Mali ti Ìdìtẹ̀gbàjọba náà ti wáyé rí ti ikọ̀ ajaguntà Russian Wagner group se ìrànwọ́ nínú ìdojú ìjà ko ọlọ̀tẹ̀.

Putin fẹ́ kí ìjọba padà sí ọ̀dọ̀ ẹni ti àwọn èniyàn yàn sí ipò, ṣùgbọ́n olórí ikọ̀ ti Wagner group, Yevgeny Prigozhin ní ìfẹ́ si ti àwọn adìtẹ̀gbàjọba. O dùn láti gbọ́ pé, àwọn ikọ̀ adìtẹ̀gbàjọba ti Niger ń fi àsìá orílẹ̀-èdè Russia pé àwọn ni wọ́n fara mọ́.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button