Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Gombe: Èwe, Aláboyún Yóò Jẹ́ Anfààní Ògùn Ibà

0 268

 

Àwọn èwe àti Aláboyún bi igba ẹgbẹ̀rún
ni won yóò jẹ ànfààní ògùn ibà ọ̀fẹ́ ipele àkọ́kọ́ ètò -Maternal New Born Child Health Week and Seasonal Malaria Chemoprevention ti ìjọba ìpínlẹ̀ Gombe gbékalẹ̀.

Àjọ elétò ìlera ti ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú State Primary Healthcare Development Agency ni wọ́n gbé ètò náà kálẹ̀ sí Primary Health Care Centre, Lalaipido, ní ìjọba ìbílẹ̀ Shongom.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ètò ìlera ọlọ́sọ̀sẹ̀, akọ̀wé elétò ìlera ìpínlẹ̀ ti Primary Healthcare Development Agency, Dókítà
Abdulrahaman Shuaibu, sọ pé àwọn èwe láti ọmọ ọdún mẹ́fà sí oṣù mọ́kàndínlọ́gọ́ta yóò jẹ anfààní Vitamin A asaralóore.

Bí ó se sọ, èròngbà ètò náà wà fún láti jẹ́ kí ikú àwọn obìnrin àti àwọn ògo wẹẹrẹ lo lẹ̀.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button