Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu fi Keyamo rọ́pò Mínísítà Kano tí wọ́n yàn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 405

 Ààrẹ Bọla Tinubu ti yọ Mínísítà Kano tí wọ́n yàn, Dokita Maryam Shettima, tí ó sì fi Dokita Mariya Mahmoud tó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ kannáà rọ́pò.

Ààrẹ tun yan minisita fun iṣẹ ati igbanisiṣẹ nigba kan ri, Festus Keyamo, SAN, lati ipinlẹ Delta.

Ààrẹ ilé igbimọ Godswill Akpabio ka Igbesẹ yii jade ní ọjọ́ Abamẹta, lori pẹpẹ pupa ile.

Yiyan to ṣẹṣẹ waye bayii wa jẹ ki akojọ orukọ awọn Minisita jẹ mejidin-laadọta, ti eleyi si tako akojọ orukọ mejile-logoji, ti o pọ julọ lati igba ti ijọba tiwantiwa ti pada ni  1999.

Ààrẹ  ko sọ idi pato fun irọpo Dokita Shettima, ẹni ti o wa lara ipele keji awọn mọkandin-logun ti wọn fi siwaju ile-igbimọ ní ọjọ́ọ́rú fún agbeyẹwo ati ibuwọlu bii Minisita.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button