Take a fresh look at your lifestyle.

Olùdíje tó ju mílíọ́nù kan lọ ṣe ìdánwò alábájáde ilé ìwé gíga 2023

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 467

Olùdíje tó ju mílíọ́nù kan lọ ló forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò alábájáde ilé ìwé gíga 2023, SSCE, tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, tí ìgbìmọ̀ elétò ìdánwò orílẹ̀-èdè NECO, ń ṣagbátẹrù rẹ̀.

Adari/Alaṣẹ apapọ NECO, Ọjọgbọn Dantani Wushishi sọ eleyi ni Jos, ipinlẹ Plateau, ní ọjọ Abamẹta nigba ti o n ṣabẹwo si awọn ile-iwe ti wọn ti n kọ idanwo naa.

Ọjọgbọn Wushishi tun sọ pe awọn oludije okunrin pọ ju awọn oludije obinrin lọ.

Inu rẹ dun fun ìdánwò alábájáde ilé ìwé gíga SSCE 2023 ṣe lọ, gẹgẹ bi iroyin ti o gbọ jakejado orilẹ-ede.

Adari naa sọ pe; “ ìdánwò alábájáde ilé ìwé gíga SSCE 2023 ti yoo pari lọsẹ to n bọ jẹ eyi ti wọn ṣeto rẹ lọna to darajulọ SSCE laarin ọdun to sunmọ.”

Ọjọgbọn Wushishi sọ pe wọn ti gbe igbesẹ loriṣiriṣi lati ṣayẹwo aṣemaṣe lasiko idanwo, ti o si fi kun un pe “ igbesẹ naa sì ti n so eso rere.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button