Take a fresh look at your lifestyle.

Gusau Bẹ́ Àwọn Olùkọ́ní FIFA Látí Ṣé Ìrànlọ́wọ́ Fún Ìdàgbàsókè Àwọn Àfọn-fèèrè Nàìjíríà

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 358

Ààrẹ tí Àjọ Àwọn Àgbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà (Nigeria Football Federation NFF) Alhaji Ibrahim Gusau ní Ọjọ́bọ̀ pé àwọn olùkọní FIFA ti wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún àwọn ètò mẹ́ta kàn, látí ṣé ìrànlọ́wọ́ látí mú ìlọsíwájú bá àwọn Olùdarí èrè bọ́ọ̀lù ní Nàìjíríà láti dé ìpele tí wọ́n yóò tí ní anfààní látí kópa nínú èrè bọ́ọ̀lù FIFA àtí CAF.

Nígbàtí o nsọ̀rọ ní ọfiisi rẹ̀ làkókò tí wọ́n ṣé àbẹ̀wò sí, Gusau bẹ̀ àwọn olùkọní náà ọmọ orílẹ̀-èdè Zambia, Morocco, Mozambique àti Djibouti látí máa wá àyè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìgbàgbogbo.

Àwọn olùkọ́ní FIFA náà ní, Gladys Lengwe ọmọ orílẹ̀-èdè Zambia tó jẹ́ olórí, Houssein Ali Mohamed látí Djibouti, Said Nouri látí Morocco àti Bento Navesse látí Mozambique. Ní wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ṣé abojuto ètò Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣojú Àwọn Obínrin, Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣojú Futsal kàn àtí Ẹ̀kó Àwọn àfọn-fèèrè àwọn ọkunrin, èyí tó tí bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kínní oṣù keje sí ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje ọdún yíì (1st – 15th July 2023).

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button