Take a fresh look at your lifestyle.

Ọwọ́ Sìnkún Àjọ EFCC Tẹ Òṣìṣẹ́ FMC Kan Àti Àwọn Mẹ́tàdínláàdọ́ta Ni Ilú Abeokuta, Àti Afurasí Mẹ́ta Míràn Ní Ìlú Ìbàdàn

0 287

Ọwọ́ sìnkún oṣiṣẹ Àjọ to n gbógun ti ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ, EFCC Ẹkùn tí Ìbàdàn ti tẹ afurasí ọkùnrin oníjìbìtì orí ẹrọ ayélujára kan ti orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Balogun Olawale, tíì ṣe Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Ijoba Àpapọ̀, Federal Medica Centre tó wà ní agbègbè Idi-Aba ni ìlú Abeokuta, tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ogun ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Bákan náà ni ọwọ́ sìnkún Àjọ náà tun tẹ àwọn afurasí Mẹ́tàdínláàdọ́ta míràn látàrí bi wọ́n ṣe lọwọ sí jìbìtì orí ẹrọ ayélujára ni agbègbè náà.

Àtẹ̀jáde kan lati ọwọ́ Adarí Ìròyìn àti Ìpolongo fún Àjọ náà ni Ẹkùn Ìbàdàn, Wilson Uwujaren ló fi ìròyìn náà ṣọwọ́ sí àwọn akọroyin ni ìlú Ìbàdàn, nínú èyí tí o ti sàlàyé pé pánpẹ́ Àjọ EFCC gba àwọn afurasí náà mú ní ọjọ́Rú, ọjọ́ Kẹrinla oṣù Kẹfà ọdún yìí ni agbègbè Idi-Aba ní ìlú Abéòkúta lẹ́yìn iṣẹ́ ìwádìí alágbára tó ṣe àfihàn irúfẹ́ iṣẹ́ ti wọ́n n ṣe.

Lára àwọn ohun tí wọn ká mọ àwọn afurasí náà lọwọ ni Ọkọ ayọkẹlẹ méje, Ọpọlọpọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ alágbèéká, ẹrọ kọmputa agbeletan, ẹrọ ibaraẹnisọrọ alágbèéká iPhone àti aago ọrùn ọwọ́.

Bákan náà ní pánpẹ́ Òṣìṣẹ́ Àjọ EFCC tún gba àwọn afurasí oníjìbìtì míràn tí wọ́n mọ sí ‘Ọmọ Yahoo’ mú ní ọjọ́ kan náà ní agbègbè Idi-Igba ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí wọ́n sì ká ọkọ̀ ayọkẹlẹ méjì àti àwọn ohun mère-mère míràn mọ́ wọn lọwọ.

Àtẹ̀jáde náà tún sàlàyé wí pé, ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ jọwọ afurasí kan fún Àjọ EFCC lórí ẹsun jibiti orí ẹrọ ayélujára, pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ‘Honda Civic’ kan àti ẹrọ ibaraẹnisọrọ alágbèéká ti wọn ká mọ ọ lọwọ.

Atejade naa jẹ kó di mímọ pé, gbogbo àwọn afurasí náà ni yóò f’ojú ba ilé ẹjọ́ lẹyin ti iṣẹ́ ìwádìí bá ti parí

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button