Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà tí Orílẹ̀-èdè Sudan sọ pé o kéré jù ènìyàn mẹ́tadìnlogùn 17 ló tí dá’gbéré f’ayé tí àwọn ọgọrùnlémẹ́fa 106 mìíràn tí f’àrápá lẹyìn tí àwọn rọkẹ̀ẹ́tì kọlù ọjà kàn ní gúúsù tí Olú-ìlú Khartoum.
Ìròyìn sọ pé, èyí ní ìyé ènìyàn tó pọ̀jù lọ́ tó kù níbí ikọlù ní àyíká Olú-ìlú látí ìgbàtí wàhálà tí bẹ̀rẹ̀ láàrín ọmọ ogún Sudan àtí àwọn ológun Àlàtìlẹ́yìn RSF, ní ọjọ́ kẹ̀ẹ́dogùn, Oṣù Kẹrìn, Ọdún 2023.
Ikọlù náà wáyé lẹyìn Ìjíròrò àdéhùn ìparí ìjà tó foriṣọpan lójú Orílẹ̀-èdè Saudi Arabia àtí America.
Tún kà nípa:Àjọ Àgbáyé (UN) Ń Béèrè Fún Bílíọ̀nù Mẹ́ta-Dín-Díẹ Dọla ($2.6B) Fún Iṣẹ́ Ọmọnìyàn Ni Sudan
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́rún dín díẹ̀ 883 àwọn aráàlú ní wọ́n tí pàdánù ẹ̀mí wọ́n látí ìgbà tí ìjà náà tí bẹ́sílẹ̀.
Leave a Reply