Take a fresh look at your lifestyle.

Igbákejì ààrẹ Ọṣinbajo ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 229

Àpèjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ọ́rú,ní ilé ìgbìmọ̀ ààrẹ,ní Villa, Àbújá, tí Igbákejì ààrẹ Yẹmi Ọṣinbajo ń ṣadarí rẹ̀.

Àpèjọ èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́wàá òwúrọ̀ jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta sí ìparíi ìgbìmọ̀ ìṣàkóso ààrẹ Muhammadu Buhari, léyìí tí yóò wá sópin ní ọjọ́ kọkàndín-lọ́gbọ̀n,oṣù Ebìbì.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọṣinbajo ni ó ń darí àpèjọ náà nítorí pé ààrẹ Buhari ṣì wà ní United Kingdom.

Ààrẹ ti lọ sí United Kingdom láti darapọ̀ mọ́ àwọn adarí tókù lágbàáyé láti kópa nínú ìwúyè Ọba Charles kẹta,ní ọjọ́ kẹfà,oṣù Ebìbì, 2023.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó darapọ̀ mọ́ àwọn Mínísítà ni;Akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha àti ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibrahim Gambari.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button