INEC, tí kéde Onímọ̀ẹ̀rọ Yakubu Danladi-Salihu, ti APC gẹ́gẹ́ bi Olubori Ìbò tí ẹkùn Ipinlẹ Ilesha-Gwanara nígbà ti ó fi ìbò rẹ tí Oludije Akin Ẹ̀gbẹ rẹ ti PDP, Usman Abubakar dànù.
Yakubu Danladi ni Agbẹnusọ Ilé igbimọ Aṣojú Ṣofin ti Ìpínlẹ̀ Kwara.
Ìkéde yi wáyé ni Ojúkò Kíkà ibo ni Gbùngbùn Ẹkùn Ilesha/Gwanara ni àgbègbé Ilé Ẹ̀kọ́ Alákọbẹ̀rẹ̀ ijoba Ibílẹ I Ipinlẹ Gwanara ti Aṣojú INEC, Dọ́kítà Adewale Rafiu kéde wípé Ìbò Danladi-Salihu jẹ́ ẹgbã mẹdogun dín mọkanlelaadọta (14,949) ti Ìbò Alátakò rẹ Usman Abubakar si jẹ Ẹgbẹ̀rún méjì le Èjìlelọgọrin (2,072).
Nínú ọ̀rọ̀ Imọyi Àti Idupẹ Danladi-Salihu, ó dúpẹ́ gidigidi lọwọ àwọn ènìyàn Ẹkùn Ilesha-Gwanara fún Ìfọwọsowọpọ fun Àṣeyọrí rẹ. Ó fí dáwọn loju wípé, èéto Ààbò ati Àlàáfíà wọn yóò jẹ́ òkùnkùndùn fún ohùn ati lati ṣíṣẹ takuntakun si. O tẹ̀síwájú láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwọn Ọba Aláayè – HRH Alhaji Abdullah Idris; ti Gwanara, HRH Ọjọ́gbọ̀n Halidu Abubakar; ti Ilesha Baruba and HRH Alhaji Idris Abubakar; ti Okuta fún atilẹyin, ìfẹ́ ati ìdúró tí wọ́n. Àwọn Ojiṣẹ Ọlọ́run. Ẹ̀gbẹ Òṣèlú APC àwọn Agbatẹrù Òṣèlú yí, àti àwọn ènìyàn ìjọba Ibílẹ Baruten lapapọ. O si pínnù làti ṣíṣẹ takuntakun jù tì àtẹ̀yìnwá lọ.
Olubunmi Adeyẹmọ.
Leave a Reply