Mínísítà fún ìròyìn àtí Àṣà tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Alhaji Lai Mohammed tí gbà àwọn oníròyìn àti aráàlú níyànjú láti yàgò fún ìròyìn ẹ̀lẹ̀jẹ̀ pàápàá jùlọ lórí àbájáde ìbò lórí ìkànnì ayélujára.

Èyí ló sọ dì mímọ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìlú àbínibí rẹ̀, Oro, Ìpínlẹ̀ Kwara lẹyìn tó dìbo tán nínú ìdìbò Ààrẹ àtí tí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà Orílẹ̀-èdè yìí.
Bẹ́ẹ̀ ló rọ àwọn aṣojú ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan àtí àwọn olúdìbò pé kí wọ́n ṣé ojúṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nígbà tó ń sọrọ lórí bí ètò ìdìbò ṣé ń lọ́ ní ẹ̀kà ìbò rẹẹ̀, Mínísítà náà sọ pé ètò náà ń lọ́ ní irọwọ àtí irọse, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olúdìbò ló tú jáde láti dìbo, Ó sí tẹ̀ òún lọrùn.
Lekan Orenuga
Leave a Reply