Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Sókótó ṣẹ̀dá ilé iṣẹ́ mẹ́fà tuntun

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 202

Lórí akitiyan rẹ̀ láti ṣe àtúntò àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ fún ṣíṣe iṣẹ́ tó múnádóko ní àwọn ilé-iṣẹ́ẹ gbogbogbòò ti ìpínlẹ̀ Sókótó,gómìnà Àmínù Wázírì Tambuwal,ti fọwọ́sí ṣíṣẹ̀dá àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba mẹ́fà tuntun,tí ó sì tún darí àwọn Kọmísọ́nà rẹ̀ láti ṣalámójútó wọn.

Àwọn ilé-iṣé tuntun náà ni: ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ọrọ̀ ajé ayélujára,ìdàgbàsókè ìṣẹ̀dá àti kátà-kárà,ọmọnìyàn àti àjọṣepọ̀ àlááfíà,ààbò inú ìlú,lílọ bíbọ̀,àti ilé-iṣẹ́, ìṣòwò àti ìdókòwò.

Bí wọn yóò ṣe ṣẹ àmójútó àwọn ilé-iṣẹ́ náà ni : Dókítà Kulu Haruna Abubakar, kọmísọ́nà fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ, yóò ṣàmójútó ilé isẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ọrọ̀-Ajé ayélujára tuntun,tí Àmínù Ibrahim yóò sì máa ṣàkóso ilé-iṣẹ́ ìdàgbàsókè ìṣẹ̀dá àti káta ̀-kárà; gẹ́gẹ́ bí Aṣojú ṣòfin  Abubakar Abdullahi Dange, yóò sì jẹ́ Kọmísọ́nà fún ètò ọmọnìyàn àti àjọṣepọ̀ àlàáfíà.

Bákannáà,Kọmísọ́nà fún ètò ààbò  inú-ìlú,lílọ bíbọ̀,ilé-iṣẹ́ ìsòwò àti ìdókòwò,ni: Aṣojú Abubakar Maikudi Ahmed, aṣojú Alhassan Ibrahim Rarah àti Aṣojú Abdullahi Yusuf Hausawa ní sísẹ̀ntẹ̀lè.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button