Igbákejì ààrẹ Ọ̀ṣínbàjò yóò kópa nínú àpèjọ adarí ọ̀dọ́ ní Liberia
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Igbákejì ààrẹ,Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò yóò jẹ́ àlajò pàtàkì níbi àpèjọ tí wọ́n pè ní “ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú igbákejì ààrẹ àti àwọn ọ̀dọ́,” tí ẹnìkejì rẹ̀ ti Liberia Dokita Jewel Howard-Taylor ṣagbátẹrù rẹ̀.
Àtẹ̀jáde kan láti ọ́fíísì igbákejì ààrẹ sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbàjò fi Àbújá sílẹ̀ ní àwúrọ̀ ọjọ́ Ajé lọ sí orílẹ̀-èdè Liberia fún àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ kan.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé igbákejì ààrẹ yóò tún ṣe ìpàdé lórí orílẹ̀-èdè méjéèjì pẹ̀lú ààrẹ George Weah ti Liberia.
Níbi àpèjọ náà èyí tí ó jẹ́ apákan àwọn ètò láti ṣàyajọ̀ ọjọ́bìí ọgọ́ta ọdún Dókítà Howard-Taylor,ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣínbàjò àti àwọn adarí iwọ̀ oòrùn Áfíríkà yóò fikùnlukùn pẹ̀lú ẹgbẹ́ irínwó àwọn adarí tuntun.
Àwọn adarí tuntun náà yóò máa “pin agbara wọn,igbiyanju,aṣeyọri.”
Leave a Reply